Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 8:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Yóò ṣi ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrin àwọn aláìkọlà, ẹ̀yin ilé Júdà, àti ilé Íṣrẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”

14. Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà.

15. “Bẹ́ẹ̀ ni èmi ṣí tí ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jérúsálẹ́mù, àti fún ilé Júdà: ẹ má bẹ̀rù.

16. Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: Ẹ ṣọ̀rọ̀ òtítọ́, olúkúlúkù sí ẹnikejì rẹ̀; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín.

17. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkeji rẹ̀; ẹ má fẹ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí.

18. Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.

19. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ààwẹ̀ oṣù kẹrin, ìkárun-un, kéje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀, àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Júdà; nítorí náà, ẹ fẹ́ otítọ́ àti àlàáfíà.”

20. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn ènìyàn yóò ṣa tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú-ńlá púpọ̀.

21. Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú-ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojú rere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’

22. Nítòótọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jérúsálẹ́mù; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojú rere Olúwa.”

Ka pipe ipin Sekaráyà 8