Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ààwẹ̀ oṣù kẹrin, ìkárun-un, kéje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀, àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Júdà; nítorí náà, ẹ fẹ́ otítọ́ àti àlàáfíà.”