Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sekaráyà 10:5-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrinalágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun,nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn,wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.”

6. “Èmi o sì mú ilé Júdà ní agbára,èmi o sì gba ilé Jósẹ́fù là,èmi ó sì tún mú wọn padànítorí mo tí ṣàánú fún wọn,ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tìí ta wọ́n nù;nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn,èmi o sì gbọ́ ti wọn

7. Éfúráímù yóò sì ṣe bí alágbára,ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí-wáìnì:àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í,wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.

8. Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ;nítorí èmi tí rà wọ́n padà;wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bíwọ́n tí ń pọ̀ sí í rí.

9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn kákiri orílẹ̀-èdè:ṣíbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jínjìn;wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn,wọn ó sì tún padà.

10. Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítìpẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Áṣíríà:èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì àti Lébánónì; aa kì yóò sì rí àyè fún wọn bí ó ti yẹ.

11. Wọn yóò sì la òkun wàhálà já,yóò sì lu rírú omi nínú òkun,gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ,a ó sì rẹ ìgbéraga Áṣíríà ṣílẹ̀,ọ̀pá aládé Éjíbítì yóò sí lọ kúrò.

12. Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa;wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Sekaráyà 10