Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanáyà 2:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Móábù,àti ẹlẹ́yà àwọn Ámónì,àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi,tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn.

9. Nítorí náà, bí Èmi tí wà,”ni Olúwa Sódómù wí, Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì,“Ní tòótọ́ Móábù yóò dàbí Sódómùàti Ámónì yóò sì dàbí Gòmórà,ibi tí ó kún fún yèrèpèàti ihó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé.Ìyòókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn;àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi niyóò jogún ilẹ̀ wọn.”

10. Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn,nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa alágbára ṣe ẹlẹ́yà.

11. Olúwa yóò jẹ́ ìbẹ̀rù fún wọn;nígbà tí Òun bá pa gbogbo òrìṣa ilẹ̀ náà run.Orílẹ̀-èdè láti etí odò yóò máa sìn,olúkúlùkù láti ilẹ̀ rẹ̀ wá.

12. “Ẹ̀yin Etiópíà pẹ̀lú,a ó fi idà mi pa yín.”

13. Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ sí apá àríwá,yóò sì pa Ásíríà run,yóò sì sọ Nínéfè di ahoro,àti di gbígbẹ bí ihà.

14. Agbo ẹran yóò sì dùbúlẹ̀ ṣíbẹ̀àti gbogbo ẹ̀dá ní orísìírísìí.Òwìwí ihà àti dídún bí ẹyẹ òwìwíyóò wọ bí ẹyẹ ni ọwọ́n rẹ̀.Ohùn wọn yóò kọrin ni ojú fèrèsé,ìdahoro yóò wà nínú ìloro ẹnu ọ̀nà,òun yóò sì ṣẹ́ kédárì sílẹ̀.

15. Èyí ni ìlú aláyọ̀ tí ó ń gbé láìléwu.Ó sì sọ sí ara rẹ̀ pé,“Èmi ni, kò sì sí ẹnìkan tí ó ń bẹ lẹ́yìn mi.”Irú ahoro wo ni òun ha ti jẹ́,ibùgbé fún àwọn ẹranko igbó!Gbogbo ẹni tí ó bá kọjá ọ̀dọ̀ rẹ̀yóò fi rẹ́rìnín ẹlẹ́yà,wọ́n yóò sì gbọn ẹsẹ̀ wọn.

Ka pipe ipin Sefanáyà 2