Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sefanáyà 2:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. kí a tó lé yín kúrò bí èrò ìyàngbò ọkà,kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín, kíọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín.

3. Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà,ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pa láṣẹ.Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú,bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.

4. Nítorí pé, a ó kọ Gásà sílẹ̀,Áṣíkélónì yóò sì dahoro.Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Áṣídódù jáde,a ó sì fa Ékírónì tu kúrò.

5. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń gbé etí òkun,ẹ̀yin ènìyàn ara Kérétì;Ọ̀rọ̀ Olúwa dojúkọ ọ́, ìwọ Kénánì,ilẹ̀ àwọn ara Fílísítíà.Èmi yóò pa yín run,ẹnìkan kò sì ní ṣẹ́kù nínú yín;

6. Ilẹ̀ náà ní etí òkun, ni ibùgbé àwọn ará Kérétì,ni yóò jẹ́ ibùjókòó fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn àti agbo àgùntàn.

7. Agbègbè náà yóò sì jẹ́ ti ìyókù àwọn ilé Júdà,níbẹ̀ ni wọn yóò sì ti rí ìjẹ fún ẹran,Ní ilé Áṣíkélónì ni wọn yóòdùbúlẹ̀ ni àṣálẹ́. Olúwa Ọlọ́run wọn yóò bojútó wọn,yóò sì yí ìgbékùn wọn padà.

8. “Èmi ti gbọ́ ẹ̀gàn Móábù,àti ẹlẹ́yà àwọn Ámónì,àwọn tó kẹ́gàn àwọn ènìyàn mi,tí wọ́n sì ti gbé ara wọn ga sí agbègbè wọn.

9. Nítorí náà, bí Èmi tí wà,”ni Olúwa Sódómù wí, Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì,“Ní tòótọ́ Móábù yóò dàbí Sódómùàti Ámónì yóò sì dàbí Gòmórà,ibi tí ó kún fún yèrèpèàti ihó iyọ̀ àti ìdahoro títí láéláé.Ìyòókù àwọn ènìyàn mi yóò kó wọn;àwọn tí ó sì yọ nínú ewu ní orílẹ̀-èdè mi niyóò jogún ilẹ̀ wọn.”

10. Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà padà nítorí ìgbéraga wọn,nítorí wọ́n kẹ́gàn, wọn sì ti fi àwọn ènìyàn Olúwa alágbára ṣe ẹlẹ́yà.

Ka pipe ipin Sefanáyà 2