Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Sáàmù 40:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlàsin ní àyà mi,èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́àti ìgbàlà Rẹ̀:èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀àti òtítọ́ Rẹ̀ mọ́kúrò láàrin àwọn ìjọ ńlá.

11. Ìwọ má ṣe,fa àánú Rẹ̀ tí ó rọnúsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwajẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ Rẹàti òtítọ́ Rẹkí ó máa pa mí mọ́títí ayérayé.

12. Nítorí pé àìníye ibini ó yí mi káàkiri,ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,títí tí èmi kò fi ríran mọ́;wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13. Jẹ́ kí ó wù ọ́,ìwọ Olúwa,láti gbà mí là; Olúwa,yára láti ràn mí lọ́wọ́.

14. Gbogbo àwọn wọ̀nnìni kí ojú kí ó tìkí wọn kí ó sì dààmúàwọn tí ń wá ọkàn miláti parun:jẹ́ kí a lé wọn padà sẹ́yìnki á sì dójú tì wọ́n,àwọn tí n wá ìpalára mi.

15. Jẹ́ kí àwọn tí ó wí fún mi pé, “Áà! Áá!”ó di ẹni àfọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí ìtijú wọn.

Ka pipe ipin Sáàmù 40