orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní orí ìbùsùn mi ní òrumo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

2. Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;Èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

3. Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí miBí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”

4. Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀Ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.Mo dì í mú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọtítí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi

5. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,Mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín búkí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókèkí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú

6. Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wábí ìkuku èéfíntí a ti fi òjíá àti tùràrí kùn lárapẹ̀lú gbogbo ètù olóòórùn oníṣòwò?

7. Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Sólómónì,Àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,Àwọn akọni Ísírẹ́lì,

8. Gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,Idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,Wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru

9. Sólómónì ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;Ó fi igi Lébánónì ṣe é.

10. Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀Ó fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀Ó fi elésè àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,Inú rẹ̀ ni ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.”

11. Ẹ jáde wá, ẹyin ọmọbìnrin Ṣíónì,kí ẹ sì wo ọba Sólómónì tí ó dé adé,Adé tí ìyá rẹ̀ fi dé eNí ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,Ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.