orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Orin Sólómónì 8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin misí mi èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà!Èmi ìbá rí ọ ní òde,èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu,wọn kì bá fi mi ṣe ẹlẹ́yà.

2. Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyámi, ìwọ ìbá kọ́ mièmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòrùn dídùn fún ọ muàti oje èso pómégíránéètì mi.

3. Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi,ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbá mí mọ́ra.

4. Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, èmi pè yín ní ìjà,Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè,Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.

5. Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti ihà,tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde;níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.

6. Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdìbí èdìdì lé apá rẹ;nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,ìjowú sì le bí isà òkújíjò rẹ̀ rí bí ìjò iná,gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ iná Olúwa.

7. Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;Bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátapáta.

8. Àwa ní arábìnrin kékeré kan,òun kò sì ní ọmú,kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa,ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?

9. Bí òun bá jẹ́ ògiri,Àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí.Bí òun bá jẹ́ ilẹ̀kùn,Àwa yóò fi pákó kédárì dí i

10. Èmi jẹ́ ògiri,ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.

11. Sólómónì ní ọgbà àjàrà kan ní Báálí-Hómónìó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́júolúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wáẹgbẹ̀rún fàdákà.

12. Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi;ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Sólómónì,igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

13. Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà,àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ,Jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!

14. Yára wá, Olùfẹ́ mi,kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin,tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín,lórí òkè òórùn dídùn.