Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 3:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Mo sì tún rí ohun mìíràn níabẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,òdodo ni ó wà ní bẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ní o wà ní bẹ̀.

17. Mo rò nínú ọkàn mi,“Ọlọ́run yóò mú ṣẹ sí ìdájọ́Olótìítọ́ pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀,Nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,àti àsìkò fún gbogbo ìṣe.”

18. Mo tún ro pe “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fi hàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí.

19. Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò ṣàn ju ẹranko lọ, nítorí pé aṣán ni yíyè jẹ́ fún wọn.

20. Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí.

21. Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ní?”

22. Nígbà náà, ni mo wá ríi wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí. Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-in rẹ̀ kò sí!

Ka pipe ipin Oníwàásù 3