Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 9:28-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Gáálì ọmọ Ébédì dáhùn pé, “Ta ni Ábímélékì tàbí tani Ṣékémù tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubu-Báálì kọ́ ní ṣe tàbí Ṣébútì kọ́ ní igbá kejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hámórì baba àwọn ará Ṣékémù, Èéṣe tí a ó fi sin Ábímélékì?

29. Bí àwọn ènìyàn yìí bá wà ní abẹ́ ìsàkóso mi ni! Ẹ̀yin ó bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín (Èmi yóò yọ Ábímélékì kúrò). Èmi ó ò wí fún Ábímélékì pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ”

30. Nígbà tí Ṣébúlù, alákoṣo ìlú náà gbọ́ ohun tí Gáálì ọmọ Ébédì sọ, inú bí i gidigidi.

31. Ó ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé, “Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣékémù ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti sọ̀tẹ̀ sí ọ.

32. Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sá pamọ́ dè wọ́n nínú igbó.

33. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí oòrùn ti ń yọ ìwọ yóò wọ inú ìlú náà lọ láti bá a jà. Yóò sì ṣe nígbà tí Gáálì àti àwọn ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá jáde sí ọ láti bá ọ jà, ìwọ yóò ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ sí wọn.”

34. Ábímélékì àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ sì jáde ní òru, wọ́n sì lúgọ (sápamọ́) sí ọ̀nà mẹ́rin yí Ṣékémù ká.

35. Gáálì ọmọ Ébédì jáde síta, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà ní àkókò tí Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jáde kúrò níbi tí wọn sá pamọ́ sí.

36. Nígbà tí Gáálì rí àwọn ènìyàn náà, ó sọ fún Ṣébúlù pé, “Wòó, àwọn ọkùnrin kan ń bọ̀ wá, láti orí àwọn òkè!”Ṣébúlù dá a lóhùn pé, “àṣìṣe lò ǹ ṣe oò ríi dáadáa, òjìji òkè ni ò ń pè ní àwọn ènìyàn.”

37. Gáálì ké ó ní, “Wòkè, àwọn ènìyàn ń tọ̀ wá bọ̀ láti agbede-méjì ilẹ̀ wá àti ẹ̀gbẹ́ kan n sì ń bọ̀ láti ìhà igi àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ń jẹ́ óákù-Méónénímù.”

38. Nígbà náà ni Ṣébúlù dá a lóhùn pé, “Níbo ni ẹnu tí ó ń ṣe ni wà báyìí. Ṣe bí o wí pé, ‘Ta ni Ábímélékì tí àwa ó fi máa sìn ín?’ Àwọn ẹni tí ó gàn án kọ́ nìyí? Jáde lọ kí o sì bá wọn jà!”

39. Gáálì sì ṣíwájú àwọn ogun ará Ṣékémù lọ kọjú Ábímélékì láti bá wọn jagun.

40. Ábímélékì sì lé e, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun ṣubú wọ́n sì gbọgbẹ́ bí wọ́n ṣe ń sáá lọ, títí dé ẹnu ọ̀nà ibùdó ìlú náà.

41. Ábímélékì dúró sí Árúmà, nígbà tí Ṣébúlù lé Gáálì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kúrò ni Ṣékémù, kò sì jẹ́ kí wọ́n gbé Ṣékémù mọ́.

42. Ní ọjọ́ kejì àwọn ará Ṣékémù sì jà lọ́ sí oko, ẹnìkan ló ṣe òfófó rẹ̀ fún Ábímélékì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 9