Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 9:21-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Lẹ́yìn tí Jótamù ti sọ èyí tan, ó sá àṣálà lọ sí Béérì, ó sì gbé níbẹ̀ nítorí ó bẹ̀rù arákùnrin rẹ̀ Ábímélékì.

22. Lẹ́yìn tí Ábímélékì ti ṣe àkóso Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́ta,

23. Ọlọ́run rán ẹ̀mí búburú sáàárin Ábímélékì àti àwọn ará Ṣékémù, àwọn ẹni tí ó hu ìwà ọ̀tẹ̀.

24. Ọlọ́run ṣe èyí láti gbẹ̀san àwọn ìwà búburú, àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀ àwọn àádọ́rin (70) ọmọ Jérúbù-Báálì lára Ábímélékì arákùnrin wọn àti lára àwọn ènìyàn Ṣékémù, ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́ láti pa àwọn arákùnrin rẹ̀.

25. Nítorí ìkórira tí wọ́n ni sí àwọn olórí, ni Ṣékémù dẹ àwọn ènìyàn sí àwọn orí òkè láti máa dá àwọn ènìyàn tó ń kọja lọ́nà, kí wọn sì máa jà wọ́n lólè, àwọn kan ló sọ èyí fún Ábímélékì.

26. Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá sí Ṣékémù, àwọn ará Ṣékémù sì gbàgbọ́ wọ́n sì fi inú tán wọn.

27. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde lọ sí oko, wọ́n sì ṣa èṣo àjàrà wọn jọ, wọ́n fún èṣo àjàrà náà, wọ́n si ṣe àjọ̀dún nínú ilé òrìṣà wọn. Nígbà tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n ń mu wọ́n fi Ábímélékì ré.

28. Gáálì ọmọ Ébédì dáhùn pé, “Ta ni Ábímélékì tàbí tani Ṣékémù tí àwa ó fi sìn ín? Ọmọ Jerubu-Báálì kọ́ ní ṣe tàbí Ṣébútì kọ́ ní igbá kejì rẹ̀? Ẹ má sin àwọn ará Hámórì baba àwọn ará Ṣékémù, Èéṣe tí a ó fi sin Ábímélékì?

29. Bí àwọn ènìyàn yìí bá wà ní abẹ́ ìsàkóso mi ni! Ẹ̀yin ó bọ́ àjàgà rẹ̀ kúrò ní ọrùn yín (Èmi yóò yọ Ábímélékì kúrò). Èmi ó ò wí fún Ábímélékì pé, ‘Kó gbogbo àwọn ogun rẹ jáde láti jà.’ ”

30. Nígbà tí Ṣébúlù, alákoṣo ìlú náà gbọ́ ohun tí Gáálì ọmọ Ébédì sọ, inú bí i gidigidi.

31. Ó ránṣẹ́ sí Ábímélékì pé, “Gáálì ọmọ Ébédì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wá láti máa gbé ní Ṣékémù ṣùgbọ́n, wọ́n ń rú àwọn ènìyàn sókè láti sọ̀tẹ̀ sí ọ.

32. Wá ní òru kí ìwọ àti àwọn ogun rẹ sá pamọ́ dè wọ́n nínú igbó.

33. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù bí oòrùn ti ń yọ ìwọ yóò wọ inú ìlú náà lọ láti bá a jà. Yóò sì ṣe nígbà tí Gáálì àti àwọn ogun rẹ̀ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ bá jáde sí ọ láti bá ọ jà, ìwọ yóò ṣe ohunkóhun tí o bá fẹ́ sí wọn.”

34. Ábímélékì àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ sì jáde ní òru, wọ́n sì lúgọ (sápamọ́) sí ọ̀nà mẹ́rin yí Ṣékémù ká.

35. Gáálì ọmọ Ébédì jáde síta, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ibodè ìlú náà ní àkókò tí Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jáde kúrò níbi tí wọn sá pamọ́ sí.

36. Nígbà tí Gáálì rí àwọn ènìyàn náà, ó sọ fún Ṣébúlù pé, “Wòó, àwọn ọkùnrin kan ń bọ̀ wá, láti orí àwọn òkè!”Ṣébúlù dá a lóhùn pé, “àṣìṣe lò ǹ ṣe oò ríi dáadáa, òjìji òkè ni ò ń pè ní àwọn ènìyàn.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 9