Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 9:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan Ábímélékì ọmọ Jérúbù-Báálì lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin ìyá rẹ̀ ní Ṣékémù ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ àti gbogbo àwọn ìbátan ìyá rẹ̀ wí pé,

2. “Ẹbi gbogbo àwọn ará Ṣékémù léèrè, ‘Èwo ló sàn fún un yín, ṣé kí gbogbo àwọn àádọ́rin ọmọ Jérú-Báálì jọba lórí yín ni tàbí kí ẹnìkan ṣoṣo ṣe àkóso yín?’ Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé ẹran ara yín àti ẹ̀jẹ̀ yín ni èmi ń ṣe.”

3. Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ èyí ní etí àwọn ará Ṣékémù, ọkàn wọn fà sí àti tẹ̀lé Ábímélékì torí, wọ́n sọ wí pé, “Arákùnrin wa ní í ṣe.”

4. Wọ́n fún un ní àádọ́rin ṣékélì fàdákà láti ilé òrìṣà Bááli-Béritì, Ábímélékì fi owó náà gba àwọn jàǹdùkú àti aláìníláárí ènìyàn tí wọ́n sì di olùtẹ̀lé rẹ̀.

5. Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ófírà, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jérú-Báálì, ṣùgbọ́n Jótamù, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jérúb-Báálì, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́.

6. Gbogbo àwọn ará Ṣékémù àti àwọn ará Bẹti-Mílò pàdé pọ̀ ní ẹ̀bá igi óákù ní ibi òpó ní Ṣékémù láti fi Ábímélékì jọba.

7. Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jótamù, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gérísímì lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbààgbà Ṣékémù, kí Olúwa le tẹ́tí sí yín.

8. Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti yan ọba fún ara wọn. Wọ́n pe igi Ólífì pé, ‘Wá ṣe ọba wa.’ ”

9. “Ṣùgbọ́n igi Ólífì dá wọn lóhùn pé, ‘Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣolórí àwọn igi?’

10. “Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jọba ní orí wa.’

Ka pipe ipin Onídájọ́ 9