Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 21:18-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Àwa kò le fi àwọn ọmọbìnrin wa fún wọn ní aya, nítorí tí àwa ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe ìbúra yìí pé: ‘Ègún ni fún ẹnikẹ́ni tí ó fi aya fún ẹnikẹ́ni nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.’ ”

19. Wọ́n sì wí pé, “Kíyèsí i ayẹyẹ ọlọ́dọọdún fún Olúwa wà ní Ṣílò ní ìhà àríwá Bẹ́tẹ́lì àti ìhà ìlà oòrùn òpópó náà tí ó gba Bẹ́tẹ́lì kọjá sí Ṣékémù, àti sí ìhà gúṣù Lébónà.”

20. Wọ́n sì fi àṣẹ fún àwọn ará Bẹ́ńjámínì pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fara pamọ́ nínú àwọn ọgbà àjàrà

21. kí ẹ sì wà ní ìmúrasílẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin Ṣílò bá jáde láti lọ dara pọ̀ fún ijó, kí ẹ yára jáde láti inú àwọn ọgbà àjàrà wọ̀n-ọn-nì kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbé aya kan nínú àwọn ọmọbìnrin Ṣílò kí ẹ padà sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì.

22. Nígbà tí àwọn baba wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn bá fi ẹjọ́ sùn wá, àwa yóò wí fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe wá lóore nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́, nítorí àwa kò rí aya fún wọn ní àkókò ogun, ẹ̀yin kò sì ní jẹ̀bi, nítorí pé ẹ̀yin kọ́ ni ó fi àwọn ọmọbìnrin yín fún wọn bí aya.’ ”

23. Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀. Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn.

24. Ní àkókò náa, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé àti ẹ̀yà rẹ̀ olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.

25. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, kò sí ọba ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì; olúkúlùkù sì ń ṣe bí ó ti tọ́ ní ojú ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 21