Onídájọ́ 21:23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
Èyí sì ni ohun tí àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà ń jó lọ́wọ́, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan mú ọmọbìnrin kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì gbé e lọ láti di aya rẹ̀. Wọ́n sì padà sí ilẹ̀ ìní wọn, wọ́n sì tún àwọn ìlú náà kọ́, wọ́n sì tẹ̀dó sínú wọn.