Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 17:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà láti agbégbé òkè Éfúráímù

2. sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tótó kílógírámù mẹ́talá tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣépè (gégùn ún). Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o.”Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Kí Olúwa bùkún ọ ọmọ mi!”

3. Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí Olúwa fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.”

4. Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba (200) ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà. Wọ́n sì kó wọn sí ilé Míkà.

5. Ọkùnrin náà, Míkà sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra èwù Éfódì kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀.

6. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́.

7. Ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì kan wà, ẹni tí ó wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, ẹni tí ó ti ń gbé ní àárin ẹ̀yà Júdà,

8. fi ìlú náà sílẹ̀ láti wá ibòmíràn láti máa gbé. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Míkà nínú àwọn ilẹ̀ òkè Éfúráímù.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 17