Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 16:6-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Torí náà Dẹ̀lílà sọ fún Sámúsónì pé, “Sọ àsírí agbára ńlá rẹ fún mi àti bí wọ́n ti le dè ọ́, àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ.”

7. Sámúsónì dá a lóhùn wí pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fi okùn tútù méje tí ẹnìkan kò sá gbẹ dè mí, èmi yóò di aláìlágbára bí i gbogbo àwọn ọkùnrin yóòkù.”

8. Àwọn olóyè Fílístínì sì mú okùn tútù méje tí ẹnikẹ́ni kò sá gbẹ wá fún Dẹ̀lílà òun sì fi wọ́n dè é.

9. Nígbà tí àwọn ènìyàn tí sá pamọ́ sínú yàrá, òun pè pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì ti dé láti mú ọ.” Ṣùgbọ́n òun já àwọn okùn náà bí òwú ti í já nígbà tí ó bá wà lẹ́bàá iná. Torí náà wọn kò mọ àsírí agbára rẹ̀.

10. Dẹ̀lílà sì sọ fún Sámúsónì pé, ìwọ ti tàn mí; o sì purọ́ fún mi. Wá báyìí kí o sì sọ bí a ti ṣe le dè ọ́.

11. Òun dáhùn pé, “Bí wọ́n bá lè fi okùn túntún tí ẹnikẹ́ni kò tíì lò rí dì mí dáadáa, èmi yóò di aláìlágbára, èmì yóò sì dàbí àwọn ọkùnrin yóòkù.”

12. Dẹ̀lílà sì mú àwọn okùn túntún, ó fi wọ́n dì í. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Fílístínì ti fi ara pamọ́ sínú yàrá, òun kígbe sí i pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ,” òun sì já okùn náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ bí òwú.

13. Dẹ̀lílà sì tún sọ fún Sámúsónì pé, “títí di ìsinsìn yìí ìwọ sì ń tún tàn mí, o sì tún purọ́ fún mi. Sọ fún mi ọ̀nà tí wọ́n fi le dè ọ́,”Sámúsónì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ bá hun ìdí irun méjèèje tí ó wà ní orí mi pẹ̀lú okùn, tí ó sì le dáadáa kí o sì fi ẹ̀mú mú un mọ́lẹ̀, èmi yóò di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yòkù.” Nígbà tí òun ti ṣùn, Dẹ̀lílà hun àwọn ìdí irun méjèèje tí ó wà ní oríi rẹ̀,

14. ó sì fi ìhunṣọ dè wọ́n.Ó sì tún pè é pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ.” Òun sì jí ní ojú oorun, ó sì fa ìdè ìhunṣọ náà tu pẹ̀lú ohun gbogbo tí wọ́n fi kàn án mọ́lẹ̀.

15. Dẹ̀lílà sì sọ fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wí pé, èmi fẹ́ràn rẹ, nígbà tí ìwọ kò fi ọkàn tán mi. Èyí ni ìgbà kẹta tí ìwọ ti tàn mí jẹ, tí ìwọ kò sì sọ àsírí ibi tí agbára ńlá rẹ gbé wà fún mi.”

16. Ó sì ṣe nígbà tí ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí dé bi pé ó ṣú u dé òpin ẹ̀mí rẹ̀.

17. Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Násírì, ẹni ìyàṣọ́tọ̀ fún Olúwa ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yóòkù.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 16