Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 16:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Sámúsónì wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé,“Ọlọ́run wa ti fi ọ̀ta walé wa lọ́wọ́.Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ waẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.”

25. Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Sámúsónì wá kí ó wá dáwa lára yá. Wọ́n sì pe Sámúsónì jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn.Nígbà tí wọ́n mú un dúró láàárin àwọn òpó.

26. Sámúsónì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó di ọwọ́ rẹ̀ mú pé, “Ẹ fi mí si ibi tí ọwọ́ mi yóò ti le tó àwọn òpó tí ó gbé tẹ́ḿpìlì dúró mú, kí èmi lè fẹ̀yìn tì wọ́n.”

27. Ní àsìkò náà, tẹ́ḿpìlì yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Fílístínì wà níbẹ̀, ní ókè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) àwọ́n ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Sámúsónì bí òun ti ń ṣeré.

28. Nígbà náà ni Sámúsónì ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, rántí mi. Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Fílístínì nítorí àwọn ojú mi méjèèjì.”

29. Sámúsónì sì na ọwọ́ mú àwọn òpó méjèèjì tí ó wà láàárin gbùngbùn, orí àwọn tí tẹ́ḿpìlì náà dúró lé, ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú ọ̀kan àti ọwọ́ òsì mú èkejì, ó fi ara tì wọ́n,

30. Sámúsónì sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi kú pẹ̀lú àwọn Fílístínì!” Òun sì fi agbára ńlá tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ilé náà wó lu àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. Báyìí ni ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbà ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ.

31. Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ ní àpapọ̀ gòkè lọ wọ́n sì gbé e, wọ́n gbé e padà wá, wọ́n sì sin ín sí agbede-méjì Sórà àti Ésítaólì sínú ibojì Mánóà baba rẹ̀. Òun ti ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní ogún (20) ọdún.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 16