Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 16:19-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Òun sì mú kí Sámúsónì sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀ (dá a lóró). Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.

20. Òun pè é wí pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ.”Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìn wá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé Olúwa ti fi òun sílẹ̀.

21. Nígbà náà ni àwọn Fílístínì mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú-un lọ sí Gásà. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú.

22. Ṣùgbọ́n irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tún hù lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.

23. Àwọn ìjòyè, àwọn ará Fílístínì sì péjọ pọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dágónì ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Sámúsónì ọ̀ta wa lé wa lọ́wọ́.

24. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Sámúsónì wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé,“Ọlọ́run wa ti fi ọ̀ta walé wa lọ́wọ́.Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ waẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.”

25. Nígbà tí inú wọn dùn gidigidi tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ńlá, wọ́n pariwo pé, ẹ mú Sámúsónì wá kí ó wá dáwa lára yá. Wọ́n sì pe Sámúsónì jáde láti ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, òun sì ń ṣeré fún wọn.Nígbà tí wọ́n mú un dúró láàárin àwọn òpó.

26. Sámúsónì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí ó di ọwọ́ rẹ̀ mú pé, “Ẹ fi mí si ibi tí ọwọ́ mi yóò ti le tó àwọn òpó tí ó gbé tẹ́ḿpìlì dúró mú, kí èmi lè fẹ̀yìn tì wọ́n.”

27. Ní àsìkò náà, tẹ́ḿpìlì yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Fílístínì wà níbẹ̀, ní ókè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) àwọ́n ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Sámúsónì bí òun ti ń ṣeré.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 16