Nígbà náà ni àwọn Fílístínì mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú-un lọ sí Gásà. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú.