Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 16:15-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Dẹ̀lílà sì sọ fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wí pé, èmi fẹ́ràn rẹ, nígbà tí ìwọ kò fi ọkàn tán mi. Èyí ni ìgbà kẹta tí ìwọ ti tàn mí jẹ, tí ìwọ kò sì sọ àsírí ibi tí agbára ńlá rẹ gbé wà fún mi.”

16. Ó sì ṣe nígbà tí ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ ọ́ ní ojoojúmọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ̀ títí dé bi pé ó ṣú u dé òpin ẹ̀mí rẹ̀.

17. Òun sì sọ ohun gbogbo tí ó wà ní ọkàn rẹ̀ fún un. Ó ní, “Abẹ kò tí ì kan orí mi rí, nítorí pé Násírì, ẹni ìyàṣọ́tọ̀ fún Olúwa ni mo jẹ́ láti ìgbà ìbí mi wá. Bí a bá fá irun orí mi, agbára mi yóò fi mí sílẹ̀, èmi yóò sì di aláìlágbára bí àwọn ọkùnrin yóòkù.”

18. Nígbà tí Dẹ̀lílà ríi pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹ̀lílà ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Fílístínì pé, “Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi.” Torí náà àwọn olóyè Fílístínì padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́.

19. Òun sì mú kí Sámúsónì sùn lórí itan rẹ̀, òun sì pe ọkùnrin kan láti fá àwọn ìdì irun orí rẹ̀ méjèèje, òun sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́gun rẹ̀ (dá a lóró). Agbára rẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.

20. Òun pè é wí pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ.”Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìn wá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé Olúwa ti fi òun sílẹ̀.

21. Nígbà náà ni àwọn Fílístínì mú un, wọ́n yọ ojú rẹ̀ méjèèjì wọ́n sì mú-un lọ sí Gásà. Wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ dè é, wọ́n sì fi sí ibi iṣẹ́ ọlọ lílọ̀ nínú ilé túbú.

22. Ṣùgbọ́n irun orí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tún hù lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti fá a.

23. Àwọn ìjòyè, àwọn ará Fílístínì sì péjọ pọ̀ láti ṣe ìrúbọ ńlá sí Dágónì ọlọ́run wọn àti láti ṣe ayẹyẹ wọ́n wí pé, ọlọ́run wa ti fi Sámúsónì ọ̀ta wa lé wa lọ́wọ́.

24. Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Sámúsónì wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé,“Ọlọ́run wa ti fi ọ̀ta walé wa lọ́wọ́.Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ waẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 16