Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 14:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó sì lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, inú Sámúsónì sì yọ́ sí i.

8. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin,

9. ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà.

10. Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Sámúsónì sì ṣe àṣè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà.

11. Nígbà tí ó fara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́.

12. Sámúsónì sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtúmọ̀ rẹ̀ láàárin ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àdìtú náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n (30) ìpàrọ̀ aṣọ ìyàwó.

13. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpàrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.”Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.”

14. Ó dáhùn pé,“Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá;láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.”Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtúmọ̀ sí àlọ́ náà.

15. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Sámúsónì, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòsì tàbí kó wa lẹ́rú ni?”

16. Nígbà náà ni ìyàwó Sámúsónì ṣubú lé e láyà, ó sì sunkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! o kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi.”“Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”

17. Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sunkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtúmọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀

Ka pipe ipin Onídájọ́ 14