Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 14:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀.

7. Ó sì lọ bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, inú Sámúsónì sì yọ́ sí i.

8. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, nígbà tí ó padà lọ láti gbé e níyàwó, ó yà lọ láti wo òkú kìnìún náà. Inú rẹ̀ ni ó ti bá ọ̀pọ̀ ìṣù oyin àti oyin,

9. ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà.

10. Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Sámúsónì sì ṣe àṣè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà.

11. Nígbà tí ó fara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́.

12. Sámúsónì sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtúmọ̀ rẹ̀ láàárin ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àdìtú náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n (30) ìpàrọ̀ aṣọ ìyàwó.

13. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpàrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.”Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.”

14. Ó dáhùn pé,“Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá;láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.”Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtúmọ̀ sí àlọ́ náà.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 14