Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 14:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Baba rẹ̀ sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti kí obìnrin náà. Sámúsónì sì ṣe àṣè gẹ́gẹ́ bí àṣà ọkọ ìyàwó ní àkókò náà.

11. Nígbà tí ó fara hàn, tí àwọn ènìyàn náà rí i wọ́n fún un ní ọgbọ̀n àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti wá bá a kẹ́gbẹ́.

12. Sámúsónì sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtúmọ̀ rẹ̀ láàárin ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àdìtú náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n (30) ìpàrọ̀ aṣọ ìyàwó.

13. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò bá le sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi, ẹ̀yin yóò fún mi ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun àti ọgbọ̀n ìpàrọ̀ aṣọ ìgbéyàwó.”Wọ́n dáhùn pé, “Sọ àlọ́ rẹ fún wa jẹ́ kí a gbọ́.”

14. Ó dáhùn pé,“Láti inú ọ̀jẹun ni ohun jíjẹ ti jáde wá;láti inú alágbára ni ohun dídùn ti jáde wá.”Ṣùgbọ́n fún odidi ọjọ́ mẹ́ta ni wọn kò fi rí ìtúmọ̀ sí àlọ́ náà.

15. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Sámúsónì, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòsì tàbí kó wa lẹ́rú ni?”

16. Nígbà náà ni ìyàwó Sámúsónì ṣubú lé e láyà, ó sì sunkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! o kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi.”“Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”

17. Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sunkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtúmọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀

18. Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé,“Kí ni ó dùn ju oyin lọ?Kí ni ó sì lágbára ju kìnìún lọ?”Sámúsónì dá wọn lóhùn pé,“Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ màlúù mi kọ ilẹ̀,ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.”

19. Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí Olúwa bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Ásíkélónì, ó pa ọgbọ̀n (30) nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru.

20. Wọ́n sì fi ìyàwó Sámúsónì fún ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ nígbà ìgbéyàwó rẹ̀.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 14