Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 12:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. wọ́n ó wí fún un pé, “Ó dá à wí pé ‘Ṣhíbólétì.’ ” Tí ó bá ní, “Síbólé,” tì torí pé kò ní mọ̀ọ́ pé dáadáa, wọ́n á mú-un wọn, a sì pa á ni àbáwọdò Jọ́dánì. Àwọn ará Éfúráímù tí wọn pa ní àkókò yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìléní-ogójì ọkùnrin.

7. Jẹ́fítà ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà Jẹ́fítà ará Gílíádì kú, wọ́n sì sin ín sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú Gílíádì.

8. Lẹ́yìn Jẹ́fítà, Íbísánì ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe ìdájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

9. Ó ní ọgbọ̀n (30) ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin fún àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n àwọn ọmọbìnrin fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin lára àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà rẹ̀. Ó ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì fún ọdún méje.

10. Lẹ́yìn náà ni Íbísánì kú, wọ́n sì sin ín sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.

11. Lẹ́yìn rẹ̀, Élónì ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì ṣe àkóso Ísírẹ́lì fún ọdún mẹ́wàá.

12. Élónì sì kú, wọ́n sì sin ín sí Áíjálónì ní ilẹ̀ Ṣébúlúnì.

13. Lẹ́yìn rẹ̀ ni Ábídónì ọmọ Hiélì tí Pírátónì n ṣe àkóso Ísírẹ́lì.

14. Òun ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọ ọmọ àwọn tí ó ń gun àádọ́rin (70) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó ṣe ìdájọ́ Ísírẹ́lì ní ọdún mẹ́jọ.

15. Ábídónì ọmọ Híélì sì kú, wọ́n sin ín sí Pírátónì ní ilé Éfúráímù ní ìlú òkè àwọn ará Ámálékì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 12