26. Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hítì, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lúsì èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.
27. Àwọn ẹ̀yà Mánásè sì kùnà láti lé àwọn tí ń gbé Bẹti-Sésínì àti àwọn ìlú agbègbè wọn jáde, tàbí àwọn ará Tánákì àti àwọn ìgbéríko rẹ̀, tàbí àwọn olùgbé Mégídò àti àwọn ìgbéríko tí ó yí i ká torí pé àwọn ará Kénánì ti pinnu láti máa gbé ìlú náà.
28. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kénánì sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà.
29. Éfúráímù náà kò lé àwọn ará Kénánì tí ó ń gbé Géṣérì jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kénánì sì ń gbé láàrin àwọn ẹ̀yà Éfúráímù.
30. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Ṣébúlúnì náà kò lé àwọn ará Kítírónì tàbí àwọn ará Nẹ́hálólì ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Ṣébúlúnì.
31. Bẹ́ẹ̀ ni Áṣérì kò lé àwọn tí ń gbé ní Ákò àti Áhálábì àti Ákísíbì àti Hélíbáhà àti Háfékì àti Réhóbù.
32. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn Áṣérì ń gbé láàrin àwọn ará Kénánì tí wọ́n ni ilẹ̀ náà.
33. Àwọn ẹ̀yà Náfítalì pẹ̀lú kò lé àwọn ará Bétì-Ṣémésì àti Bẹti-Ánátì jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Náfítanì náà ń gbé àárin àwọn ará Kénánì tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Bẹti-Ṣéméṣì àti Bẹti-Ánátì ń sìn ìsìn tipátipá.
34. Àwọn ará Ámórì fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dánì dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀.