Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 1:21-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọn kò le lé àwọn Jébúsì tí wọ́n ń gbé Jérúsálẹ́mù nítorí náà wọ́n ń gbé àárin àwọn Ísírẹ́lì títí di òní.

22. Àwọn ẹ̀yà Jóṣẹ́fù sì bá Bẹ́tẹ́lì jagun, Olúwa ṣíwájú pẹ̀lú wọn.

23. Nígbà tí ẹ̀yà Jóṣẹ́fù rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Bẹ́tẹ́lì wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lúsì).

24. Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àti wọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mìí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.”

25. Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si.

26. Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hítì, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lúsì èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.

27. Àwọn ẹ̀yà Mánásè sì kùnà láti lé àwọn tí ń gbé Bẹti-Sésínì àti àwọn ìlú agbègbè wọn jáde, tàbí àwọn ará Tánákì àti àwọn ìgbéríko rẹ̀, tàbí àwọn olùgbé Mégídò àti àwọn ìgbéríko tí ó yí i ká torí pé àwọn ará Kénánì ti pinnu láti máa gbé ìlú náà.

28. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kénánì sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà.

29. Éfúráímù náà kò lé àwọn ará Kénánì tí ó ń gbé Géṣérì jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kénánì sì ń gbé láàrin àwọn ẹ̀yà Éfúráímù.

30. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà Ṣébúlúnì náà kò lé àwọn ará Kítírónì tàbí àwọn ará Nẹ́hálólì ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Ṣébúlúnì.

31. Bẹ́ẹ̀ ni Áṣérì kò lé àwọn tí ń gbé ní Ákò àti Áhálábì àti Ákísíbì àti Hélíbáhà àti Háfékì àti Réhóbù.

32. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn Áṣérì ń gbé láàrin àwọn ará Kénánì tí wọ́n ni ilẹ̀ náà.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 1