Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 9:8-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Mósè sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pa láṣẹ nípa yín.”

9. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé,

10. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá mọ́.

11. Wọn yóò ṣe ti wọn ní ìdajì ọjọ́ kẹ́rìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro.

12. Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣẹ àjọ Ìrékọjá.

13. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

14. “ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrin yín bá fẹ́ ṣe Àjọ Ìrékọjá ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”

15. Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkúùkù àwọ̀sánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkúùkù náà sì dàbí iná lórí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀.

16. Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe títí, ìkúùkù yóò bò ó lọ́sán, ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná lálẹ́.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 9