Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 8:3-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Árónì sì ṣe bẹ́ẹ̀; ó to àwọn fìtílà náà tí wọ́n sì fi kojú ṣíwájú lórí ọ̀pá fìtílà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

4. Bí a ṣe ṣe ọ̀pá fìtílà náà nìyìí: A ṣe é láti ara wúrà lílù: láti ìṣàlẹ̀ títí dé ibi ìtànná rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà náà gẹ́gẹ́ bí bátànìi tí Olúwa fi han Mósè.

5. Olúwa sọ fún Mósè pé:

6. “Yọ àwọn ọmọ Léfì kúrò láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, kí o sì wẹ̀ wọ́n mọ́.

7. Báyìí ni kí o ṣe wẹ̀ wọ́n mọ́: Wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ sí wọn lára, mú kí wọn ó fá irun ara wọn, kí wọn ó fọ aṣọ wọn, kí wọn ó ba à lè wẹ ara wọn mọ́ nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

8. Jẹ́ kí wọn ó mú akọ ọ̀dọ́ màlúù pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ tí í ṣe ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò, kí ìwọ náà mú akọ ọ̀dọ́ màlúù kejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

9. Ìwọ ó sì mú àwọn ọmọ Léfì wá ṣíwájú Àgọ́ Ìpàdé, kí o sì kó gbogbo àpapọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì jọ ṣíbẹ̀ pẹ̀lú.

10. Báyìí ni kí o mú àwọn ọmọ Léfì wá ṣíwájú Olúwa, gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì yóò sì gbọ́wọ́ lé àwọn ọmọ Léfì lórí.

11. Árónì yóò sì mú àwọn ọmọ Léfì wá ṣíwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa.

12. “Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Léfì bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Léfì.

13. Mú kí àwọn ọmọ Léfì dúró níwájú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa.

14. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Léfì sọ́tọ̀, kúrò láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, àwọn ọmọ Léfì yóò sì jẹ́ tèmi.

15. “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé.

16. Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátapáta nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkunrin gbogbo Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 8