Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 5:2-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.

3. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má báà ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrin wọn”

4. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mósè.

5. Olúwa sọ fún Mósè pé:

6. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìsòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi.

7. Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn ún rẹ̀ lée, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀.

8. Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó sún mọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà

9. Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀.

10. Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti oun nikan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”

11. Olúwa sọ fún Mósè wí pé,

12. “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé: ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìsòótọ́ sí i,

13. Nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lò pọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà).

14. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ débi pé ó ń furà sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́,

15. nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n éfà ìyẹ̀fun bálì. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.

16. “ ‘Àlùfáà yóò sì mú-un wá ṣíwájú Olúwa.

17. Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀,

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 5