Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 4:14-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èèlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwo kòtò. Kí wọn ó fi àwọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpo rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

15. “Lẹ́yìn tí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀ṣíwájú, kí àwọn ọmọ Kóhátì bọ́ ṣíwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kóhátì ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú Àgọ́ Ìpàdé.

16. “Iṣẹ́ Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àmójútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́.”

17. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,

18. “Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kóhátì kúrò lára àwọn ọmọ Léfì:

19. Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má baà kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálukú àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé.

20. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kóhátì kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”

21. Olúwa sọ fún Mósè pé:

22. “Tún ka iye àwọn ọmọ Gáṣónì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

23. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.

24. “Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gáṣónì, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù:

25. Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti Àgọ́, ti Àgọ́ Ìpàdé àti ìborí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé,

26. Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà, okùn àti àwọn ohun èlò mìíràn tí à ń lò fún gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí. Àwọn ọmọ Gáṣónì ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí.

27. Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gáṣónì yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un.

28. Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gáṣónì ni Àgọ́ Ìpàdé Ítamárì, ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn.

29. “Ka iye àwọn ọmọ Mérárì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 4