Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 29:7-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “ ‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpèjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó ṣẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

8. Kí ẹ̀yin kí ó rú ẹbọ olóòrùn dídùn sí Olúwa, ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kan, kí wọn kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù fún yín.

9. Pẹ̀lú akọ màlúù, pèsè ìdámẹ́wàá mẹ́ta, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò àti ìdámẹ́wàá méjì òṣùwọ̀n fún àgbò kan,

10. àti fún ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan, ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n.

11. Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù àti ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ mímu wọn.

12. “ ‘Ní ijọ́ kẹẹdógún oṣù kéje, kí ẹ̀yin kí ó ní àpèjọ mímọ́, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó ṣi ṣe àjọyọ̀ fún Olúwa fún ọjọ́ méje.

13. Kí ẹ sì rú ẹbọ sísun kan, ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ tí ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù mẹ́tàlá, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ó jẹ́ ọdún kan, tí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù.

14. Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù mẹ́tàlá, pèsè ìyẹ̀fun òṣùwọ̀n ìdámẹ́wàá mẹ́ta tí a fi òróró pò pẹ̀lú ọ̀kọ̀kan, fún àgbò kan, bẹ́ẹ̀ ni fún àgbò méjèèjì,

15. àti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn kan. Bẹ́ẹ̀ ni fún ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá.

16. Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ọrẹ sísun gbogbo ìgbà ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu rẹ̀.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 29