Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 26:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. ti Hésírónì, ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì;ti Kárímì, ìdílé àwọn ọmọ Kárímì.

7. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730).

8. Àwọn ọmọkùnrin Pálù ni Élíábù,

9. àwọn ọmọkùnrin Élíábù ni Némúélì àti Dátanì àti Ábírámù. Èyí ni Dátanì àti Ábírámù náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Árónì tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.

10. Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kórà, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tàlérúgba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀.

11. Àwọn ọmọ Kórà, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.

12. Àwọn ọmọ ìrán Símónì bí ìdílé wọn:ti Némúélì, ìdílé Némúélì;ti Jámínì, ìdílé Jámínì;ti Jákínì, ìdílé Jákínì;

13. ti Ṣérà, ìdílé Ṣérà;tí Ṣọ́ọ̀lù, ìdílé Ṣọ́ọ̀lù.

14. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Símónì, ẹgbàámọ́kànlá ó lé igba. (22,200) ọkùnrin.

15. Àwọn ọmọ Gádì bí ìdílé wọn:ti Ṣéfónì, ìdílé Ṣéfónì;ti Hágígì, ìdílé Hágígì;ti Ṣúnì, ìdílé Ṣúnì;

16. ti Ósínì, ìdílé Ósíní;ti Érì, ìdílé Érì;

17. ti Árédì, ìdílé Árédì;ti Árólì, ìdílé Árólì.

18. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gádì tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 26