Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 26:54-65 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

54. Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ.

55. Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni ín.

56. Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrin ńlá àti kékeré.”

57. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Léfì tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Gáṣónì, ìdílé àwọn ọmọ Gáṣónì;ti Kóhátì, ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì;ti Mérárì, ìdílé àwọn ọmọ Mérárì.

58. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Léfì;ìdílé àwọn ọmọ Líbínì,ìdílé àwọn ọmọ Hébírónì,ìdílé àwọn ọmọ Málì,ìdílé àwọn ọmọ Múṣì,ìdílé àwọn ọmọ Kórà.(Kóhátì ni baba Ámírámù,

59. Orúkọ aya Ámírámù sì ń jẹ́ Jókébédì, ọmọbìnrin Léfì, tí ìyá rẹ̀ bí fún Léfì ní Éjíbítì. Òun sì bí Árónì, Mósè, àti Míríámù arábìnrin wọn fún Ámírámù.

60. Árónì ni baba Nádábù àti Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.

61. Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)

62. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Léfì láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.

63. Àwọn wọ̀nyí ni Mósè àti Élíásárì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá odò Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.

64. Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mósè àti Árónì àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ihà Sínáì.

65. Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kíkú ni wọn yóò kú sí ihà, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú à fi Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnì, àti Jóṣúà ọmọ Núnì.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 26