Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 26:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-àrùn Olúwa sọ fún Mósè àti Élíásárì ọmọ Árónì, àlùfáà pé

2. “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Ísírẹ́lì.”

3. Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Móábù pẹ̀lú Jọ́dánì tí ó kọjá Jẹ́ríkò, Mósè àti Élíásárì àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,

4. “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè.”Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde láti Éjíbítì wá:

5. Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àkọ́bí ọmọkùnrin Ísírẹ́lì,láti ẹni ti ìdílé Hánókù, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hánókù ti jáde wá;Láti ìdílé Pálù, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pálù ti jáde wá;

6. ti Hésírónì, ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì;ti Kárímì, ìdílé àwọn ọmọ Kárímì.

7. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé ẹgbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730).

8. Àwọn ọmọkùnrin Pálù ni Élíábù,

9. àwọn ọmọkùnrin Élíábù ni Némúélì àti Dátanì àti Ábírámù. Èyí ni Dátanì àti Ábírámù náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Árónì tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.

10. Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kórà, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tàlérúgba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀.

11. Àwọn ọmọ Kórà, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.

12. Àwọn ọmọ ìrán Símónì bí ìdílé wọn:ti Némúélì, ìdílé Némúélì;ti Jámínì, ìdílé Jámínì;ti Jákínì, ìdílé Jákínì;

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 26