Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 22:22-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, áńgẹ́lì Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Bálámù ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.

23. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí áńgẹ́lì Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Bálámù sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà.

24. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrin ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì.

25. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Bálámù mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nàá, lẹ́ẹ̀kan sí i.

26. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì.

27. Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí ángẹ́lì Olúwa, ó sì jókó ní abẹ́ Bálámù, inú sì bí i tó sì ná-àn pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀.

28. Nígbà náà Olúwa sí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Bálámù pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?”

29. Bálámù sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ì bá pa ọ́ nísinsin yìí.”

30. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Bálámù pé, “Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”“Rárá,” Ó dáhùn.

31. Nígbà náà Olúwa sí ojú Bálámù, ó sì rí ángẹ́lì Olúwa tí ó dúró ní oju ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fàyọ. Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba.

32. Nígbà náà ángẹ́lì Olúwa bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí? Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi.

33. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí mi ó sì yà kúrò fún mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta yìí. Tí ó bá jẹ́ wí pé kò yà kúrò. Èmi kì ìbá ti pa ọ́ pátapáta nísinsìnyìí, ṣùgbọ́n Èmi yóò sì dá òun sí.”

34. Bálámù sọ fún ángẹ́lì Olúwa pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, èmi kò mọ̀ pé o dúró níwájú ọ̀nà láti dojú kọ mí, Nísinsin yìí tí inú rẹ kò bá dùn, èmi ó padà.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 22