Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 21:4-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hórì lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Édómù. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà;

5. wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Olúwa àti Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì kí a ba le wá kú sí ihà yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kóríra oúnjẹ tí kò dára yìí!”

6. Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárin wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kú.

7. Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mósè wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a sọ̀rọ̀ òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mósè gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.

8. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”

9. Nígbà náà ni Mósè sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

10. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì péjọ sí Óbótì.

11. Wọ́n gbéra ní Óbótì wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-àbárímù, ní ihà tí ó kọjú sí Móábù ní ìdojúkọ ìlà oòrùn.

12. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní àfonífojì Sérédì.

13. Wọ́n gbéra kúrò níbẹ̀ wọ́n sì pa ibùdó sí ẹ̀bá ọ̀nà Ánónì, tí ó wà ní Ìfà-gùn ihà tó kángun sí ibi tí ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámórì wa. Ánónì jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Móábù, láàrin Móábù àti Ámórì.

14. Ìdí nì yìí tí ìwé ogun Olúwa ṣe wí pé:“…Wáhébù ní Súpà, òkun pupa àtiní odò Ánónì

15. àti ní isà odò tí ó darí sí ibùjókòó Árítí ó sì fara ti ìpìnlẹ̀ Móábù.”

16. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Béérì, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mósè, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”

17. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì kọ orin yìí pé:“Sun jáde, ìwọ kànga!Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,

18. Nípa kanga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́,nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ẹ:tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fiọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.”Nígbà náà wọ́n kúrò láti ihà lọ sí Mátanà,

19. láti Mátanà lọ sí Náhálíẹ́lì, láti Náhálíẹ́lì lọ sí Bámótì,

20. àti láti Bámótì lọ sí àfonífojì ní Móábù níbi tí òkè Písígà, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí ihà.

21. Ísírẹ́lì rán oníṣẹ́ láti sọ fún Síhónì ọba àwọn ará Ámórì wí pé:

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 21