Wọ́n gbéra kúrò níbẹ̀ wọ́n sì pa ibùdó sí ẹ̀bá ọ̀nà Ánónì, tí ó wà ní Ìfà-gùn ihà tó kángun sí ibi tí ilẹ̀ àwọn ọmọ Ámórì wa. Ánónì jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Móábù, láàrin Móábù àti Ámórì.