Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 21:14-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ìdí nì yìí tí ìwé ogun Olúwa ṣe wí pé:“…Wáhébù ní Súpà, òkun pupa àtiní odò Ánónì

15. àti ní isà odò tí ó darí sí ibùjókòó Árítí ó sì fara ti ìpìnlẹ̀ Móábù.”

16. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Béérì, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mósè, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”

17. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì kọ orin yìí pé:“Sun jáde, ìwọ kànga!Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,

18. Nípa kanga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́,nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ẹ:tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fiọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.”Nígbà náà wọ́n kúrò láti ihà lọ sí Mátanà,

19. láti Mátanà lọ sí Náhálíẹ́lì, láti Náhálíẹ́lì lọ sí Bámótì,

20. àti láti Bámótì lọ sí àfonífojì ní Móábù níbi tí òkè Písígà, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí ihà.

21. Ísírẹ́lì rán oníṣẹ́ láti sọ fún Síhónì ọba àwọn ará Ámórì wí pé:

22. “Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀ èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà tàbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”

23. Ṣùgbọ́n Síhónì kò ní jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí ihà nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí ó dé Jánásì, ó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.

24. Àmọ́ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Ánónì lọ dé Jábókù, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ámónì, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi.

25. Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ìlú Ámórì wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Hésíbónì, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.

26. Hésíbónì ni ìlú Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ó bá ọba ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Ánónì.

27. Ìdí nì yí tí akọrin sọ wí pé:“Wá sí Hésíbónì kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;jẹ́ kí ìlú Ṣíhónì padà bọ̀ sípò.

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 21