Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 5:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀ṣùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlúu yín! Nítorí náà mo pe àpèjọ ńlá láti bá wọn wí.

8. Mo sì wí fún wọn pé: “Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà. Nísinsìn yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà!” Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohun kóhun sọ.

9. Nítorí náà, mo tẹ̀ṣíwájú pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀ta wa?

10. Èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi, pẹ̀lú ń yá àwọn ènìyàn lówó àti oúnjẹ (ọkà). Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a dáwọ́ owó èlé gbígbà yìí dúró!

11. Ẹ fún wọn ní oko wọn, ọgbà àjàrà wọn, ọgbà ólífì wọn àti ilée wọn pẹ̀lú owó èlé tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ọ wọn ìdá ọgọ́rùn-ún owó, oúnjẹ (ọkà), wáìnì túntún àti òróró tí ẹ ti gbà lọ́wọ́ọ wọn padà kíákíá.”

12. Wọ́n wí pé, “Àwa yóò dá a padà.” “Àwa kì yóò sì béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ọ wọn mọ́. Àwa yóò ṣe bí o ti wí.”Nígbà náà mo pe àwọn àlùfáà, mo sì mú kí àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè búra láti jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ti ṣe ìlérí.

13. Mo sì gbọn ìṣẹ́tí aṣọ mi, mo wí pé, “Báyìí ni kí Ọlọ́run gbọn olúkúlùkù ènìyàn tí kò bá pa ìlérí yìí mọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ ìní i rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí a gbọn irú ẹni bẹ́ẹ̀ jáde kí ó sì ṣófo!”Gbogbo ìjọ ènìyàn sì wí pé “Àmín,” wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa. Àwọn ènìyàn náà sì ṣe bí wọ́n ti ṣe ìlérí.

14. Síwájú sí í, láti ogún ọdún ìjọba Aritaṣéṣéṣì, nígbà tí a ti yàn mí láti jẹ́ baálẹ̀ wọn ní ilẹ̀ Júdà, títí di ọdún kejìlélọ́gbọ̀n ìjọba rẹ̀—ọdún méjìlá, èmi àti àwọn arákùnrin mi kò jẹ oúnjẹ baálẹ̀.

15. Ṣùgbọ́n àwọn baálẹ̀ ìṣáájú—tí ó ti wà ṣáájú mi—gbe àjàgà wúwo lé àwọn ènìyàn lórí yàtọ̀ fún oúnjẹ àti wáìnì wọ́n sì tún gba ogójì ṣékélì fàdákà lọ́wọ́ wọn. Kódà àwọn ìránṣẹ́ wọn tún jẹ gàba lóríi wọn. Ṣùgbọ́n èmi kò ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Ka pipe ipin Nehemáyà 5