Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemáyà 10:21-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Méṣésábélì, Ṣádókù, Jádúyà

22. Pélátíyà, Hánánì, Hánáyà,

23. Hóséà, Hananáyà, Háṣúbù,

24. Hálóésì, Píléhà, Ṣóbékì,

25. Réhúmù, Háṣábínà, Mááséyà,

26. Áhíyà, Hánánì, Ánánì,

27. Málúkù, Hárímù, àti Báánà.

28. “Àwọn ènìyàn tó kù—àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn aṣọ́nà, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn àjèjì nítorí òfin Ọlọ́run, papọ̀ pẹ̀lú ìyàwóo wọn, gbogbo ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn, tí òye yé

29. gbogbo wọn fi ara mọ́ àwọn arákùnrin wọn, àwọn ọlọ́lá, wọ́n sì fi ègún àti ìbúra dé ara wọn láti máa tẹ̀lé òfin Ọlọ́run tí a fi fún wọn ní ipasẹ̀ Móṣè ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti láti pa gbogbo àṣẹ, ìlànà àti òfín Olúwa, wa mọ́ dáadáa.

30. “A ti ṣe ìlérí pé, a kò ní fi àwọn ọmọbìnrin wa fún àwọn tí wọ́n wà ní àyíkáa wa bí ìyàwó, tàbí fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin wa.

Ka pipe ipin Nehemáyà 10