Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Náhúmù 2:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. A pa á láṣẹ pé ìlú náà Èyí tí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ni kí a kó ní ìgbèkùn lọ.A ó sì mú un gòkè wáàti awọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ yóò ti ohùn bí ti oriri, ṣe amọ̀nà rẹ̀,wọn a sì máa lu àyà wọn.

8. Nínéfè dàbí adágún omi,tí omi wọn sì ń gbẹ́ ẹ lọ.“Dúró! Dúró!” ni wọ́n ó máa kígbe,ṣùgbọ́n ẹnikankan kì yóò wo ẹ̀yìn.

9. “Ẹ kó ìkógun fàdákà!Ẹ kó ìkógun wúrà!Ìṣúra wọn ti kò lópin náà,àti ọrọ̀ kúrò nínú gbogbo ohun èlò ti a fẹ́!”

10. Òun ti ṣòfò, ó si di asán, ó sì di ahoro:ọkàn pami, éekún ń lu ara wọn,ìrora púpọ̀ sì wà nínú gbogbo ẹgbẹ́àti ojú gbogbo wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì.

11. Níbo ni ihò àwọn kìnnìún wààti ibi ìjẹun àwọn ọmọ kìnnìún,níbi tí kìnnìún, àní abo kìnnìún ti ń rìn,àti ọmọ kìnnìún, láìsí ohun ìbẹ̀rù

12. Kìnnìún pàápàá tẹ́rù fún àwọn ọmọ rẹ̀,ó sì fún-un ní ọ́rùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀,Ó sì fi ohun pípa kún ibùgbé rẹ̀àti ihò rẹ̀ fún ohun ọdẹ.

13. “Kíyèsíi èmi dojú kọ ọ́,”ni Olúwa awọn ọmọ ogun wí.“Èmi yóò sì fi kẹ̀kẹ́ rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jóná nínú èéfín,idà yóò sì jẹ ọmọ kìnnìún rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì run.Èmi yóò sì ké ohun ọdẹ rẹ kúrò lórí ilẹ̀ ayéOhùn awọn òjíṣẹ́ rẹni a kì yóò sì tán gbọ́ mọ́.”

Ka pipe ipin Náhúmù 2