Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Míkà 2:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ègbé ni fún àwọn tí ń gbérò àìṣedéédéétí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ibi lórí ibùsùn wọn!Nígbà tí ojúmọ́ bá mọ́, wọn yóò gbé e jádenítorí ó wà ní agbára wọn láti se é.

2. Wọ́n sì ń ṣe ojúkòkòrò oko, wọ́n sì fi agbára wọn gbà wọ́n,àti àwọn ilé, wọ́n sì gbà wọ́n.Wọ́n sì ni ènìyàn àti ilẹ̀ rẹ̀ láraàni ènìyàn àti ohun ìní rẹ̀.

3. Nítorí náà, Olúwa wí pé:“Èmi ń gbérò ibi sí àwọn ìdílé wọ̀nyí,nínú èyí tí wọn kì yóò le è gba ara wọn là.Ìwọ kì yóò sì lè máa rìn ní ìgbéraga mọ́,nítorí yóò jẹ́ àkókò ibi.

4. Ní ọjọ́ náà ni ẹnìkan yóò fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;wọn yóò sì pohùn réré ẹkún kíkorò pé:‘Ní kíkó a ti kó wọn tán; Olúwa ti pín ohun ìní àwọn ènìyàn mi;Ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi!Ó fi oko wa lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́.’ ”

5. Nítorí náà, ìwọ kò ní ní ẹnìkan kan nínú ìjọ Olúwa,tí yóò pín ilẹ̀ nípa ìbò.

6. “Ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀lẹ̀,” ni àwọn Wòlíì wọn wí.“Ẹ má ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí;kí ìtìjú má ṣe le bá wa”

Ka pipe ipin Míkà 2