Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Míkà 1:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Míkà ará Mórésétì wá ní àkókò ìjọba Játamù, Áhásì, àti Heṣekáyà, àwọn ọba Júdà nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaríà àti Jérúsálẹ́mù.

2. Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,fétísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,kí Olúwa alààyè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, Olúwa láti inú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ̀ wá.

3. Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.

4. Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,àwọn àfonífojì yóò sì pín yà,bí idà níwájú iná,bí omi tí ó ń ṣàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.

5. Nítorí ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù ni gbogbo èyí,àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì.Kí ni ìré-òfin-kọjá Jákọ́bù?Ǹjẹ́ Samaríà ha kọ?Kí ni àwọn ibi gíga Júdà?Ǹjẹ́ Jérúsálẹ́mù ha kọ?

6. “Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaríà bí òkítì lórí pápá,bí ibi ti à ń lò fún gbíngbin àjàrà.Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀sẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.

7. Gbogbo àwọn ère fífín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹ́ḿpìlì rẹ̀ ni a ó fi iná sun:Èmi yóò sí pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run.Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà,gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”

8. Nítorí èyí, èmi yóò sì sunkún,èmi yóò sì pohùnréré ẹkún:èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ihòòhòÈmi yóò ké bí akátá,èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.

9. Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlewòtán;ó sì ti wá sí Júdà.Ó sì ti dé ẹnu bodè àwọn ènìyàn mi,àní sí Jérúsálẹ́mù.

10. Ẹ má ṣe sọ ní Gátìẹ má ṣe sunkún rárá.Ní ilẹ̀ Bẹti-ófíràmo yí ara mi nínú eruku.

11. Ẹ kọjá lọ ni ìhòòhò àti ni ìtìjú,ìwọ tí ó ń gbé ni Sáfírì.Àwọn tí ó ń gbé ni Sáánánìkì yóò sì jáde wá.Bétésélì wà nínú ọ̀fọ̀;A ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.

12. Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Márátì ń retí ire,Ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu bodè Jérúsálẹ́mù.

13. Ìwọ olùgbé Lákísi,dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára.Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀sí àwọn ọmọbìnrin Síónì,nítorí a rí ìré-òfin-kọjá Ísírẹ́lì nínú rẹ̀.

Ka pipe ipin Míkà 1