Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 9:8-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Árónì sì wá síbi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.

9. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ náà wá fún un, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣalẹ̀ pẹpẹ.

10. Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí Olúwa ti pá láṣẹ fún Mósè.

11. Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó.

12. Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún un ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fún, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.

13. Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.

14. Ó fọ nǹkan inú rẹ̀ àti ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó sun wọ́n lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ.

15. Árónì mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá. Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́.

16. Ó mú ẹbọ sísun wá, ó sì rú u gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a fi lélẹ̀.

17. Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀.

18. Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà fún un, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká.

19. Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tó bo ẹ̀dọ̀:

20. gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Árónì sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ.

21. Árónì fí igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mósè ṣe pa á láṣẹ.

Ka pipe ipin Léfítíkù 9