Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 8:12-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí Árónì, ó sì yà á sí mímọ́.

13. Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ Árónì wá ṣíwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dì wọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

14. Ó sì mú akọ mààlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà.

15. Mósè pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyóòkù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìṣàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un.

16. Mósè tún mú gbogbo ọ̀rá tó bo nǹkan inú, èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.

17. Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú àwọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

18. Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà.

19. Mósè sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.

20. Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ó sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀.

21. Ó fi omi fọ gbogbo nǹkan inú àti ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó sì sun odidi àgbò náà lórí pẹpẹ bí ẹbọ sísun òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná se sí Olúwa gẹ́gẹ́ bí Olúwa tí pàṣẹ fún Mósè.

22. Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí.

23. Mósè sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí ètí ọ̀tún Árónì, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹṣẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

24. Mósè sì tún mú àwọn ọmọ Árónì wá ṣíwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.

25. Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún.

26. Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà.

27. Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.

28. Lẹ́yìn náà, Mósè gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa.

Ka pipe ipin Léfítíkù 8