Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 7:21-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun aláìmọ́ yálà ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ẹranko aláìmọ́, ohun àìmọ́ yówù kí ó jẹ́ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ìríra, tí ó sì tún jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tó jẹ́ ti Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ.’ ”

22. Olúwa sọ fún Mósè pé,

23. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ ọ̀rá mààlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́

24. Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko ìgbẹ́ pa, fún nǹkan mìíràn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

25. Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ọ̀rá ẹran tí a fi rúbọ sísun sí Olúwa ni ẹ gbọdọ̀ gé kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.

26. Ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tàbí ẹran ní gbogbo ibi tí ẹ bá ń gbé.

27. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀, a ó ge ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

28. Olúwa sọ fún Mósè pé:

29. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa.

30. Pẹ̀lú ọwọ́ ara rẹ̀ ni kí ó fi mú ọrẹ tí a fi iná sun wá fún Olúwa, kí ó mú ọ̀rá àti igẹ̀, kí ó sì fi igẹ̀ yìí níwájú Olúwa bí ọrẹ fífí.

31. Àlùfáà yóò sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ ṣùgbọ́n igẹ̀ ẹran náà jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀,

32. kí ẹ fún àlùfáà ní itan ọ̀tún lára ọrẹ àlàáfíà yín gẹ́gẹ́ bí ìpín tiyín fún àlùfáà.

33. Ọmọ Árónì ẹni tí ó rúbọ ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ọrẹ àlàáfíà ni kí ó ni itan ọ̀tún gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀.

34. Nínú ọrẹ àlàáfíà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo ti ya igẹ̀ tí a fi àti itan tí ẹ mú wá sọ́tọ̀ fún Árónì àlùfáà àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní gbogbo ìgbà láti ọ̀dọ̀ ara Ísírẹ́lì.’ ”

35. Èyí ni ìpín tí a yà sọ́tọ̀ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ẹbọ tí a finá sun sí Olúwa lọ́jọ́ tí wọ́n mú wọn wá láti sin Olúwa gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

36. Lọ́jọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni Olúwa ti pa á láṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fún wọn ní àwọn nǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ìgbà gbogbo fún àwọn ìran tó ń bọ̀.

37. Nítorí náà, àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìlànà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi, ìfinijoyè àlùfáà àti ẹbọ àlàáfíà

38. èyí tí Olúwa fún Mósè lórí òkè Sínáì lọ́jọ́ tí Olúwa pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa mú ọrẹ wọn wá fún Olúwa ni asáálẹ̀ Sínáì.

Ka pipe ipin Léfítíkù 7