Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 5:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Kí ó gbé e wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà, àlùfáà yóò sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni

13. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dárí jìn-ní.’ ”

14. Olúwa sọ fún Mósè pé

15. “Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ Olúwa, kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtanràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ẹbọ ẹ̀bi ni.

16. Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ohun tí ó ti kùnà láti ṣe ní ti àwọn ohun mímọ́ Olúwa, kí ó sì fi ìdá márùn-ún kún iye ohun tí ó kùnà láti ṣe nípa ohun mímọ́ Olúwa kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà, ẹni tí yóò ṣe ètùtù fún un pẹ̀lú àgbò fún ẹbọ ẹ̀bi, a ó sì dárí jìn-ní.

17. “Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kó yẹ ko ṣe sí ọ̀kan nínú òfin Olúwa, bí kò tilẹ̀ mọ̀, ó jẹ̀bi, yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀

18. kí ó mú àgbò kan láti inú agbo ẹran wá sọ́dọ̀ àlùfáà, fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí bí iye owó ibi mímọ́. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà, fún àṣìṣe tí ó ṣe láìmọ̀, a ó sì dári jìn-ní.

Ka pipe ipin Léfítíkù 5