Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 26:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “ ‘Ẹ pa ọjọ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi: Èmi ni Olúwa.

3. “ ‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì sọ́ra láti pa òfin mi mọ́.

4. Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso.

5. Èrè oko yín yóò pọ̀ débí pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilé yín láì léwu.

6. “ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà: bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì sí ogun mọ́.

7. Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀ta yín: wọn yóò sì tipa idà kú.

8. Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa sẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn: Àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa sẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá: Àwọn ọ̀ta yín yóò tipa idà kú níwájú yín.

9. “ ‘Èmi yóò fi ojú rere wò yín: Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i: Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín.

10. Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde: kí ẹ̀yin lè rí àyè kó túntún sí.

11. Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárin yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín.

12. Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.

Ka pipe ipin Léfítíkù 26