Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 2:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “ ‘Bí ẹnìkan bá mú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ wá fún Olúwa ọrẹ rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun darádara, kí ó da òróró sí i, kí o sì fi tùràrí sí i,

2. kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Árónì tí í se àlùfáà. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

3. Ìyòókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìpín tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.

4. “ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúná dáradára, àkàrà tí a se láì ní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láì ní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò.

5. Bí ó bá jẹ́ inú àwo pẹẹrẹ ni o ti se ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára tí a fi òróró pò, kò sì gbọdọ̀ ní ìwúkàrà.

6. Rún un kí o sì da òróró síi lórí, ọrẹ ohun jíjẹ ni.

7. Bí ó bá jẹ́ inú páànù ni o ti se ọrẹ ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára àti òróró.

8. Mú ọrẹ ohun jíjẹ tí a fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe wá fún Olúwa gbé e fún àlùfáà, ẹni tí yóò gbe e lọ sí ibi pẹpẹ,

9. Àlùfáà yóò sì mú ẹbọ ìrántí nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí, yóò sì sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

10. Ìyòókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí jẹ́ ti Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.

Ka pipe ipin Léfítíkù 2