Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Léfítíkù 11:36-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Bí òkú wọn bá bọ́ sínú omi tàbí kànga tó ní omi nínú, omi náà kò di aláìmọ́ ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá yọ òkú wọn jáde tí ó fi ọwọ́ kàn-án yóò di aláìmọ́.

37. Bí òkú ẹranko wọ̀nyí bá bọ́ sórí ohun ọ̀gbìn tí ẹ fẹ́ gbìn wọ́n sì jẹ́ mímọ́.

38. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ti da omi sí ohun ọ̀gbìn náà tí òkú wọn sì bọ́ sí orí rẹ̀ àìmọ́ ni èyí fún un yín.

39. “ ‘Bí ẹran kan bá kú nínú àwọn tí ẹ lè jẹ, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú rẹ̀ yóò dí aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

40. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èyíkéyí nínú òkú ẹranko náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú ẹranko yóò fọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wà ní àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

41. “ ‘Ìríra ni gbogbo ohun tí ń rìn kákiri lórí ilẹ̀ jẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n.

42. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ń rìn ká orí ilẹ̀ yálà ó ń fàyàfà tàbí ó ń fi ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, tàbí ó ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣẹ̀ rìn ìríra ni èyí:

43. Ẹ má ṣe sọ ara yín di aláìmọ́ nípa èyíkéyí nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá wọ̀nyí. Ẹ má ṣe sọ ara yín dí àìmọ́ yálà láti ara wọn, tàbí nípaṣẹ̀ wọn.

44. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ torí pé mo jẹ́ mímọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípaṣẹ̀ ohunkóhun tí ń rìn kákiri lórí ilẹ̀.

45. Èmi ni Olúwa tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín torí náà, ẹ jẹ́ mímọ́ torí pé mímọ́ ni èmi.

Ka pipe ipin Léfítíkù 11